Saamu123yor_bib
Orin fún ìgòkè.
1Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.2Kíyèsi, bí ojú àwọnìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,títí yóò fi ṣàánú fún wa.3Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.4Ọkàn wa kún púpọ̀fún ẹ̀gàn àwọn onírera,àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.