Saamu122yor_bib
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
1Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,“Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.”2Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,ìwọ Jerusalẹmu.3Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlútí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.4Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,àwọn ẹ̀yà Olúwa,ẹ̀rí fún Israẹli,láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.5Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.6Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.7Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,àti ìre nínú ààfin rẹ̀.8Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mièmi yóò wí nísinsin yìí pé,kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀.9Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.