Saamu120yor_bib

Orin fún ìgòkè.

1Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,ó sì dá mi lóhùn.2Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èkéàti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3Kí ni kí a fi fún ọ?Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?4Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
5Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!6Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbéláàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.7Ènìyàn àlàáfíà ni mí;ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.