Saamu12yor_bib
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
1Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.2Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.3Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọnàti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu4tí ó wí pé,“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”5“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí.“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”6Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.7Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.8Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kirinígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.