Saamu113yor_bib

1Ẹ máa yin Olúwa.Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,ẹ yin orúkọ Olúwa.2Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa látiìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.3Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.
4Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.5Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,tí ó gbé ní ibi gíga.6Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wòòun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
7Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀,àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.8Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládéàní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.9Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.Ẹ yin Olúwa.