Saamu112yor_bib

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.
2Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.3Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;òdodo rẹ̀ sì dúró láé.4Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.5Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,a sì wínni;ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.
6Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.7Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.8Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.9Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú,nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.
10Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.