Saamu111yor_bib
1Ẹ máa yin Olúwa.Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.2Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.3Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.4Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.5Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.6Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.7Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.8Wọ́n dúró láé àti láé,ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.9Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.10Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,ìyìn rẹ̀ dúró láé.