Saamu11yor_bib
Fún adarí orin. Ti Dafidi.
1Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.2Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùnláti tafà níbi òjìjisí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.3Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́kí ni olódodo yóò ṣe?”4Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.5Olúwa ń yẹ olódodo wò,ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipáni ọkàn rẹ̀ kórìíra.6Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jòẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.7Nítorí, olódodo ní Olúwa,o fẹ́ràn òdodo;ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.