Saamu109yor_bib
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
1Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún,má ṣe dákẹ́,2nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tànti ya ẹnu wọn sí miwọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.3Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;wọ́n bá mi jà láìnídìí4Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.5Wọ́n sì fi ibi san ìre fún miàti ìríra fún ìfẹ́ mi.6Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọjẹ́ kí àwọn olùfisùndúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.7Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.8Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú;kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.9Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní babakí aya rẹ̀ sì di opó.10Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kirikí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.11Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó níjẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.12Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún untàbí kí wọn káàánú lóríàwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba.13Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúròkí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀.14Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kíó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa.Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.15Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwakí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.16Nítorí kò rántí láti ṣàánú,ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.17Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.18Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wùbẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi.19Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara,àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.20Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.21Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ.Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.22Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.23Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.24Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbàẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.25Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.26Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.27Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyíwí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.28Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre,nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.29Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjúkí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.30Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidiní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.31Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìníláti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.