Saamu106yor_bib

1Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fúnOlúwa, nítorí tí ó ṣeun.Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun,nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?3Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.
4Rántí mi, Olúwa,nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,5kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
6Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,a sì ti hùwà búburú.7Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.8Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹláti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.9O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.10O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn,láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.11Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn;bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.12Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
13Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣewọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.14Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.15Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fúnṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
16Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mosepẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.17Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mìó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.18Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;iná jo àwọn ènìyàn búburú.19Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúùwọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.20Wọ́n pa ògo wọn dàsí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.21Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́nẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,22iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamuàti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.23Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n runbí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náàtí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.
24Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náàwọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.25Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọnwọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.26Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókèkí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,27láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdèláti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
28Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,29wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣeàjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.30Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán.31A sì ka èyí sí òdodo fún un àtifún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀32Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.33Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run.Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
34Wọn kò pa àwọn ènìyàn rungẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,35Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.36Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọntí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.37Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọàti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.38Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ.Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani,ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.39Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
40Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀41Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.42Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójúwọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.43Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí iwọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.44Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòronígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn,45ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọnNítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.46Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùnó mú wọn rí àánú.
47Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹláti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
48Olùbùkún ni Olúwa,Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!