Saamu103yor_bib

Ti Dafidi.

1Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.2Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,3ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,4ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikúẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,5ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùnkí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fúngbogbo àwọn tí a ni lára.
7Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;8Olúwa ni aláàánú àti olóore,ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.9Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbobẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,10Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wabẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́bí àìṣedéédéé wa.11Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.12Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùnbẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,14nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.15Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó,16afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.17Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,18sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,tí ó ní ipá,tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, tì ó sì ń se ìfẹ́ rẹ̀.21Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.22Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ níibi gbogbo ìjọba rẹ̀.Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.