Saamu100yor_bib
Saamu. Fún ọpẹ́.
1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.2Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa,ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn3Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pétirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀àti àgùntàn pápá rẹ̀.4Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.5Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní ooreìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.