Òwe18yor_bib
1Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.2Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òyeṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.3Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.4Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.5Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburútàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.6Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.7Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́,ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.8Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn;wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.9Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.10Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.11Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.12Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.13Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.14Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.15Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.16Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùna sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.17Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre,títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.18Ìbò dídì máa ń parí ìjàa sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.19Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.20Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.21Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.22Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.23Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.24Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.