Òwe12yor_bib
1Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.2Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwaṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.3A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburúṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.4Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.5Èrò àwọn olódodo tọ́,ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.6Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.7A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.8A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.9Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.10Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.11Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.12Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkàṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.13A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.14Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rerebí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.15Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.16Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.17Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ ríṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.18Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.19Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláéṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.20Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburúṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.21Ibi kì í ṣubú lu olódodo ráráṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.22Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.23Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.24Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọbaṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.25Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodòṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.26Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.27Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.28Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wàní ọ̀nà náà ni àìkú wà.