Filemoni1yor_bib
Ìkíni
1Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa,Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa,2sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:3Oore-ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.