Obadiah1yor_bib
1Ìran ti Obadiah.
Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”2“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.3Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’4Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”ni Olúwa wí.5“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́,wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?6Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.7Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ,àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”8Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?9A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani,gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esauní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.10Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,ìtìjú yóò bò ọ,a ó sì pa ọ run títí láé.11Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ,tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.12Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,ní ọjọ́ ìparun wọnìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ní ọjọ́ wàhálà wọn.13Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,ní ọjọ́ àjálù wọn.Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.14Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nàláti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínúwọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.15“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílélórí gbogbo àwọn kèfèrí.Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.16Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi,bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí;wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùnwọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí.17Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni,wọn yóò sì jẹ́ mímọ́,àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.18Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ ináàti ilé Josẹfu ọwọ́ ináilé Esau yóò jẹ àgékù koríkowọn yóò fi iná sí i,wọn yóò jo run.Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.19Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò niilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.20Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaaniyóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefarediyóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní.21Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wáláti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.