Nehemiah12yor_bib
Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi
1Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tí ó bá Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua padà:Seraiah, Jeremiah, Esra,2Amariah, Malluki, Hattusi,3Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,4Iddo, Ginetoni, Abijah,5Mijamini, Moadiah, Bilgah,6Ṣemaiah, Joiaribu, Jedaiah,7Sallu, Amoki, Hilkiah, àti Jedaiah.
Wọ̀nyí ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jeṣua.8Àwọn ọmọ Lefi ni Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda àti Mattaniah ẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ni wọn ṣe àkóso orin ìdúpẹ́.9Bakbukiah àti Unni, àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró sí òdìkejì wọn nínú ìsìn.10Jeṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada,11Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jaddua.12Ní ìgbé ayé Joiakimu, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà:
ti ìdílé Seraiah, Meraiah; ti ìdílé Jeremiah, Hananiah;13ti ìdílé Esra, Meṣullamu; ti ìdílé Amariah, Jehohanani;14ti ìdílé Malluki, Jonatani; ti ìdílé Ṣekaniah, Josẹfu;15ti ìdílé Harimu, Adna; ti ìdílé Meraioti Helikai;16ti ìdílé Iddo, Sekariah; ti ìdílé Ginetoni, Meṣullamu;17ti ìdílé Abijah, Sikri; ti ìdílé Miniamini àti ti ìdílé Moadiah, Piltai;18ti ìdílé Bilgah, Ṣammua; ti ìdílé Ṣemaiah, Jehonatani;19ti ìdílé Joiaribu, Mattenai; ti ìdílé Jedaiah, Ussi;20ti ìdílé Sallu, Kallai; ti ìdílé Amoki, Eberi;21ti ìdílé Hilkiah, Haṣabiah; ti ìdílé Jedaiah, Netaneli.22Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi ní ìgbà ayé Eliaṣibu, Joiada, Johanani àti Jaddua, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dariusi ará Persia.23Àwọn olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Lefi títí di àkókò Johanani ọmọ Eliaṣibu ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.24Àti àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi ni Haṣabiah, Ṣerebiah, Jeṣua ọmọ Kadmieli, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojú wọn láti fi ìyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run.25Mattaniah, Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni àti Akkubu ni aṣọ́nà tí wọ́n ń sọ yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ní ẹnu-ọ̀nà.26Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Joiakimu ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, àti ní ọjọ́ ọ Nehemiah baálẹ̀ àti ní ọjọ́ Esra àlùfáà àti akọ̀wé.