1Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.2“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹliyóò ti jáde tọ̀ mí wá,ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,láti ìgbà láéláé.”3Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátátítí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padàláti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.4Òun yóò sì dúró,yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa,ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.Wọn yóò sì wà láìléwu,nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹyóò sì dé òpin ayé.
Ìgbàlà àti ìparun
5Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn.Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ watí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa,nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i,àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.6Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run,àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà.Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asirianígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ watí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa.7Ìyókù Jakọbu yóò sì wàláàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyànbí ìrì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa,bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko,tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàntàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.8Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlàní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn,bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó,bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn,èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.9A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀,gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun.10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,“Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹèmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.11Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run,èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.12Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.13Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run,àti ọwọ̀n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀;ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.14Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀,èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.15Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunúlórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”