1Ní ọjọ́ ìkẹyìna ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá,wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”Òfin yóò jáde láti Sioni wá,àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.3Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré.Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjéorílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.4Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.5Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
Èrò Olúwa
6“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,“Èmi yóò kó àwọn arọ jọ;èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ,àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.7Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù,èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára.Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioniláti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.8Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn,odi alágbára ọmọbìnrin Sioni,a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín;ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”9Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí?Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí?Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí?Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.10Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora,ìwọ obìnrin Sioni,bí ẹni tí ń rọbí,nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú,ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó.Ìwọ yóò lọ sí Babeli;níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà.Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.11Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ.Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́,ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”12Ṣùgbọ́n wọn kò mọèrò inú Olúwa;bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn,nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.13“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni,nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin,èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.”Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwaàti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.