Mika1yor_bib
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.2Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.