Ẹkún Jeremiah5yor_bib

1Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.2Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,ilé wa ti di ti àjèjì.3Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,àwọn ìyá wa ti di opó.4A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;igi wa di títà fún wa.5Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa;àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.6Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asirialáti rí oúnjẹ tó tó jẹ.7Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́,àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.8Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa,kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.9Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wanítorí idà tí ó wà ní aginjù.10Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò,ebi sì yó wa bí àárẹ̀.11Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.12Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.13Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.14Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.15Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.16Adé ti ṣí kúrò ní orí waègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.17Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.18Fún òkè Sioni tí ó ti di ahorolórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.
19Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé;ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.20Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?21Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,22àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátátí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.