Ẹkún Jeremiah4yor_bib
1Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,wúrà dídára di àìdán!Òkúta ibi mímọ́ wá túkásí oríta gbogbo òpópó.2Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye,tí wọ́n fi wúrà dídára ṣewá dàbí ìkòkò amọ̀ lásániṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!3Àwọn ajáko pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aginjù.4Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ,ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.5Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradáradi òtòṣì ní òpópó.Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.6Ìjìyà àwọn ènìyàn mitóbi ju ti Sodomu lọ,tí a sí ní ipò ní òjijìláìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.7Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì,wọ́n sì funfun ju wàrà lọwọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,ìrísí wọn dàbí safire.8Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú;wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.Ara wọn hun mọ́ egungun;ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.9Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sànju àwọn tí ìyàn pa;tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfòfún àìní oúnjẹ láti inú pápá.10Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánúni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹtí ó di oúnjẹ fún wọnnígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.11Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.Ó da iná ní Sionití ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.12Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,tàbí àwọn ènìyàn ayé,wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọodi ìlú Jerusalẹmu.13Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíìàti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà,tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodosílẹ̀ láàrín rẹ̀.14Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópóbí ọkùnrin tí ó fọ́jú.Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́ntí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.15“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.“Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!”Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé,“Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”16Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀;kò sí bojútó wọn mọ́.Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,àti àánú fún àwọn àgbàgbà.17Síwájú sí i, ojú wa kùnàfún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wòfún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.18Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níyenítorí òpin wa ti dé.19Àwọn tí ń lé wa yáraju idì ojú ọ̀run lọ;wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkèwọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.20Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa,ni wọ́n fi tàkúté wọn mú.Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.21Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu,ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi.Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú;ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.22Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin;kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́.Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yàyóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.