1Jobu sì dáhùn ó si wí pé,2“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!3Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.4Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,oró èyí tí ọkàn mi mú;ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?6A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?7Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.8“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.9Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.10Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.11“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?12Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?13Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?14“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?15Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lébí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.16Tí ó dúdú nítorí omi dídì,àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.17Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.18Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.19Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.20Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.21Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.22Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?23Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?24“Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.25Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tóṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?26Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣeàti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.27Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.28“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé,ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.29Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.30Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?