Jobu41yor_bib

Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú láti pe Jobu níjà

1“Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde?Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?2Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú,tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?3Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?4Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí?Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?5Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni,tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?6Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí?Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?7Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀,tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.8Fi ọwọ́ rẹ lé e lára,ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.9Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán;ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?10Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè.Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.11Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un?Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
12“Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani,tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.13Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀?Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?14Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀?Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.15Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀;ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.16Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.17Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀;wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.18Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́,ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.19Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá,ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.20Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá,bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.21Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná,ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.22Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí,àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.23Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀,wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.24Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta,àní, ó le bi ìyá ọlọ.25Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù;nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.26Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà,ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.27Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹàti idẹ si bi igi híhù.28Ọfà kò lè mú un sá;òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.29Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko;ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.30Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀,ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.31Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò;ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.32Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀;ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.33Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,tí a dá láìní ìbẹ̀rù.34Ó bojú wo ohun gíga gbogbo,ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”