1Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,2“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”3Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,4“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.5Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”6Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,7“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,èmi ó bi ọ léèrè,kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.8“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.9Ìwọ ni apá bí Ọlọ́runtàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?10Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.11Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.12Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.13Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.14Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.15“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,tí mo dá pẹ̀lú rẹ,òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.16Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.17Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.18Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.19Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.20Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.22Igi lótusì síji wọn bò o;igi arọrọ odò yí i káàkiri.23Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.24Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?