1“Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.2Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.3Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.4Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.5Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.6Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’7Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.8Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,wọn a sì wà ni ipò wọn.9Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.10Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,ibú omi á sì súnkì.11Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.12Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhuntí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.13Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.14“Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.15Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?16Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?17Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.18Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?19“Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.20A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?21Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò ríoòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.22Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.23Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.24Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”