Jobu27yor_bib
1Pẹ̀lúpẹ̀lú Jobu sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé,2“Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ,àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́,3níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi,àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.4Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké,bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.5Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre;títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.6Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́;àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.7“Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú,àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo.8Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè,nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?9Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀,nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i?10Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè?Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?11“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run:ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.12Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i;kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín?13“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run,àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè.14Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni;àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.15Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn:àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.16Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀,tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;17àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó;àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.18Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.19Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́,nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ.20Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn;ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.21Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ;àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.22Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí;òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.23Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí,wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”