1Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé,2“Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?3Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?4Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?”5“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.6Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,ibi ìparun kò sí ní ibojì.7Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.8Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.9Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.10Ó fi ìdè yí omi òkun ká,títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.11Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.12Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.13Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.14Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”