1Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,2“Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.3Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?4Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?5Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,6kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”