Jobu18yor_bib

Ìdáhùn Bilidadi

1Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn, ó sì wí pé,2“Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì;ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ.3Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko,tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?4Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀;kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi?Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?
5“Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò,ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.6Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀,fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.7Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ;ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.8Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n,ó sì rìn lórí okùn dídẹ.9Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.10A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀,a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà.11Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo,yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.12Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi,ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.13Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀;ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.14A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.15Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀;sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.16Gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀,a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.17Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé,kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.18A ó sì lé e láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn,a ó sì lé e kúrò ní ayé.19Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.20Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀-oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà-oòrùn.21Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọnènìyàn búburú, èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”