1Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé,2“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ ríayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.3Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?4Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi,èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn,èmi a sì mi orí mi sí i yín.5Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú,àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.6“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?7Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.8Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.9Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.10Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.11Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú,ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.12Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;13àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.14Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;ó súré kọlù mi bí jagunjagun.15“Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.16Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.17Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́ mi;àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.18“Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.19Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.20Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run,21ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.22“Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán,nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.”