Jobu14yor_bib

Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀

1“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.2Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.3Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?4Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?Kò sí ẹnìkan!5Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ,ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.6Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi,títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.8Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,9síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.10Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù,àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.

Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn

11“Bí omi ti í tán nínú ipa odò,àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,12bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
13“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!14Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.15Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.16Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?17A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
18“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.19Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sìmú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.20Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.21Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.22Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìroraọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”