Jeremiah9yor_bib
1Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omikí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòrunítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.2Háà, èmi ìbá ní ni aginjùilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágààjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.3Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀bí ọfà láti fi pa irọ́;kì í ṣe nípa òtítọ́ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;wọn kò sì náání mi,ní Olúwa wí.4“Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.5Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹnitó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọnláti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọndi onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀6Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn;wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,”ni Olúwa wí.7Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:“Wò ó, èmi dán wọn wo;nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe?Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?8Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;ó ń sọ ẹ̀tàn.Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀,ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.9Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san arami lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”10Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkèàti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì.Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀.A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn.Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ,bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.11“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtìàlàpà àti ihò àwọn ìkookò.Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahorotí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.”12Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?13Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.14Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.15Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.16Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”17Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:“Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá;sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.18Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,kí wọn wá pohùnréré ẹkúnlé wa lórí títí ojú wa yóòfi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa.19A gbọ́ igbe ìpohùnréréẹkún ní Sioni:‘Àwa ti ṣègbé tó!A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”20Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa;ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún,kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.21Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọléó sì ti wọ odi alágbára waó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbòàti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.22Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubúbí ààtàn ní oko gbangbaàti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórèláìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”23Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀,tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀,tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.24Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé,Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́,ìdájọ́ àti òdodo ní ayé,nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,”Olúwa wí.25“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.26Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”