Jeremiah17yor_bib
1“Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,sórí wàláà oókan àyà wọn,àti sórí ìwo pẹpẹ yín.2Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹàti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹàti àwọn òkè gíga.3Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹpẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ópọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.4Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yinyóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrúní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀,nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi,èyí tí yóò sì wà títí ayé.”5Báyìí ni Olúwa wí:“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.6Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.7“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrinnáà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fiOlúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.8Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadòtí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odòkò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutùkò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dábẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”9Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,ó kọjá ohun tí a lè wòsàn.Ta ni èyí lè yé?10“Èmi Olúwa ń wo ọkànàti èrò inú ọmọ ènìyàn,láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”11Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yéni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo.Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀,àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.12Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ní ibi ilé mímọ́ wa.13Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,orísun omi ìyè sílẹ̀.14Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,nítorí ìwọ ni ìyìn mi.15Wọ́n sọ fún mi wí pé:“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”Ni Olúwa wí.16Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.