Jeremiah1yor_bib
1Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini.2Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda,3àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.