Isaiah64yor_bib

1Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!2Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jótí ó sì mú kí omi ó hó,sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹkí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!3Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.4Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ ríkò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.5Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọnń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,tí ó rántí ọ̀nà rẹ.Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,inú bí ọ.Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?6Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;gbogbo wa kákò bí ewé,àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.7Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹtàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún waó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.9Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa,má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.10Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.11Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,ni a ti fi iná sun,àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.12Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?