Isaiah61yor_bib

Ọdún ojúrere Olúwa

1Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára minítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn míláti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùnàti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,2láti kéde ọdún ojúrere Olúwaàti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,3àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioniláti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,irúgbìn Olúwaláti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
4Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padàtí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.5Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdèàti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.
7Dípò àbùkù wọnàwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,àti dípò àbùkù wọnwọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.
8“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀.Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọnèmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.9A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdèàti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn.Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ péwọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”
10Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlàó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.11Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jádeàti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìnkí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.