Isaiah57yor_bib
1Olódodo ṣègbékò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,kò sì ṣí ẹni tó yépé a ti mú àwọn olódodo lọláti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.2Gbogbo àwọn tí ń rìn déédéń wọ inú àlàáfíà;wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.3“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?Ta ni o ń yọ ṣùtì sítí o sì yọ ahọ́n síta?Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,àti ìran àwọn òpùrọ́?5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákùàti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìnàti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídánwọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;àwọ̀n ni ìpín in yín.Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹkí n dáwọ́ dúró?7Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yínníbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.9Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifiẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’Ẹ rí okun kún agbára yín,nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.11“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rùtí ẹ fi ń ṣèké sí mi,àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mitàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?12Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ni yóò jogún ilẹ̀ náàyóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”