1Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsíàti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”3Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀mọ́ Olúwa sọ wí pé,“Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”4Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mití wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin5fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ìrántí kan àti orúkọ kantí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin,Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayétí a kì yóò ké kúrò.6Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwaláti sìn ín,láti fẹ́ orúkọ Olúwaàti láti foríbalẹ̀ fún ungbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—7àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;nítorí a ó máa pe ilé mi níilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”8Olúwa Olódùmarè sọ wí pé—ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọnyàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”
Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan àwọn ìkà
9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá,ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!10Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú,gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,wọn kò lè gbó;wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.11Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;wọn kì í ní ànító.Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye;olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀,ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.12Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì!Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yóọ̀la yóò sì dàbí òní,tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”