Isaiah52yor_bib
1Jí, jí, ìwọ Sioni,wọ ara rẹ ní agbára.Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́kì yóò wọ inú rẹ mọ́.2Gbọn eruku rẹ kúrò;dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu.Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.3Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí,“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀lọ sí Ejibiti láti gbé;láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.5“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”ni Olúwa wí.“Àti ní ọjọọjọ́orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.6Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”7Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkèẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá,tí wọ́n kéde àlàáfíà,tí ó mú ìyìnrere wá,tí ó kéde ìgbàlà,tí ó sọ fún Sioni pé,“Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”8Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókèwọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni,wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.9Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.10Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò ríìgbàlà Ọlọ́run wa.11Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí!Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúròtàbí kí ẹ sáré lọ;nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.