Isaiah5yor_bib

Orin ọgbà àjàrà náà

1Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́rànorin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kanní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.2Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúròó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.
3“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmuàti ẹ̀yin ènìyàn Judaẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àtiọgbà àjàrà mi.4Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,èéṣe tí ó fi so kíkan?5Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi.Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,a ó sì pa á run,Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.6Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoroláì kọ ọ́ láì ro ó,ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuruláti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”
7Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogunni ilé Israẹliàwọn ọkùnrin Judasì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí.Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

Ègún àti ìdájọ́

8Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́létí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kùtí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:“Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńláyóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.10Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò múìkòkò wáìnì kan wá,nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò múagbọ̀n irúgbìn kan wá.”
11Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìdení kùtùkùtù òwúrọ̀láti lépa ọtí líle,tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.12Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.13Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùnnítorí òye kò sí fún wọn,ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ.14Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sípẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.15Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.16Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.17Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
18Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,19sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,jẹ́ kí ó súnmọ́ bíjẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
20Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
21Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọntí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
22Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímuàti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,23tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.24Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko runàti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹràtí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.25Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀,ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.Àwọn òkè sì wárìrì,òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro.Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò,ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.
26Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà,yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.27Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀,kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn;bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú,bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja.28Àwọn ọfà wọn múná,gbogbo ọrun wọn sì le;pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.29Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún,wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún,wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mútí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.30Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórígẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun.Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.