1“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu,ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹlití o sì wá láti ẹ̀ka Juda,ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwatí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹliṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,2ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nìtí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli—Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.3Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀;lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.4Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin;bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.5Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’6Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn.Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí?“Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọfún ọ nípa nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.7A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’8Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bíláti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.9Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,kí a má ba à ké ọ kúrò.10Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pékì í ṣe bí i fàdákà;Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.11Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí.Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
Israẹli dòmìnira
12“Tẹ́tí sí mi, ìwọ JakọbuIsraẹli ẹni tí mo pè.Èmi ni ẹni náà;Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.13Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.14“Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́.Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.Olúwa ti fẹ́ ẹ,yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.15Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.Èmi yóò mú un wá,òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.16“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi,pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.17Èyí ni ohun tí Olúwa wí,Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.18Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.19Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúròtàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”20Fi Babeli sílẹ̀,sá fún àwọn ará Babeli,ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀kí o sì kéde rẹ̀.Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”21Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọnkọjá nínú aginjù;ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;ó fọ́ àpátaomi sì tú jáde.22“Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí,“Fún àwọn ìkà.”