Isaiah47yor_bib

Ìṣubú Babeli

1“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku,wúńdíá ọmọbìnrin Babeli;jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́,ọmọbìnrin àwọn ará Babeli.A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.2Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun;mú ìbòjú rẹ kúrò.Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan,kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.3Ìhòhò rẹ ni a ó sí sítaàti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀.Èmi yóò sì gba ẹ̀san,Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”
4Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
5“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,ọmọbìnrin àwọn ará Babeli;a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrinàwọn ilẹ̀ ọba mọ́.6Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mití mo sì ba ogún mi jẹ́,mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n.Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lúní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.7Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé—ọbabìnrin ayérayé!’Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyítàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
8“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dátí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹtí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.Èmi kì yóò di opótàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’9Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹláìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:pípàdánù ọmọ àti dídi opó.Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹàti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.10Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nànígbà tí o wí fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’11Ìparun yóò dé bá ọbẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;òfò kan tí o kò le faradà niyóò wá lójijì sí oríì rẹ.
12“Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹàti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.13Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà nió ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀láti oṣù dé oṣù,jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.14Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi;iná ni yóò jó wọn dànù.Wọn kò kúkú lè gba ara wọn làlọ́wọ́ agbára iná náà.Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbónáníhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.15Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìígbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.