Isaiah27yor_bib

Ìdáǹdè Israẹli

1Ní ọjọ́ náà,Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yàidà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbáraLefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.2Ní ọjọ́ náà,“Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.3Èmi Olúwa ń bojútó o,Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà.Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòrukí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.4Inú kò bí mi.Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun,Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”
6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,Israẹli yóò tanná yóò sì rudièso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù úgẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?Ǹjẹ́ a ti pa ágẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ófi dojúkọ ọ́pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wàfún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún tiìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹdàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrítí yóò wà ní ìdúró.10Ìlú olódi náà ti dahoro,ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tìgẹ́gẹ́ bí aginjù;níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ okoníbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànùàwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dánánítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́,nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn;bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.12Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.13Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.