Isaiah26yor_bib

Orin ìyìn kan

1Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda.Àwa ní ìlú alágbára kan,Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣeògiri àti ààbò rẹ̀.2Ṣí àwọn ìlẹ̀kùnkí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.3Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípéọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.4Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.5Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.6Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ẹsẹ̀ aninilára n nì,ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.
7Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú,ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nààwọn olódodo ṣe geere.8Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹàwa dúró dè ọ́;orúkọ rẹ àti òkìkí rẹàwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.9Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayéàwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkàwọn kò kọ́ láti sọ òdodo;kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́ntẹ̀síwájú láti máa ṣe ibiwọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.11Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókèṣùgbọ́n àwọn kò rí i.Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹkí ojú kí ó tì wọ́n;jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọnọ̀tá rẹ jó wọn run.
12Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ nió ṣe é fún wa.13Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìírànlẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí,ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.14Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́;gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.15Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa;ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.
16Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn;nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn,wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọtí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa.18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora,ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ.Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé;àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.
19Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyèara wọn yóò dìde.Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.
20Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọkí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín,ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá.21Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀;kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.