1Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sìfi ìyìn fún orúkọ rẹnítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́o ti ṣe ohun ńlá,àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.2Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,ìlú olódi ti di ààtàn,ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;a kì yóò tún un kọ́ mọ́.3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóòbọ̀wọ̀ fún ọ;àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánúyóò bu ọlá fún ọ.4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣìààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjìbòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.Nítorí pé èémí àwọn ìkàdàbí ìjì tí ó bì lu ògiri5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.6Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò ti pèsèàsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyànàpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnìtí ó gbámúṣé.7Ní orí òkè yìí ni yóò paaṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,8Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,kúrò ní ojú gbogbo wọn,Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúròní gbogbo ilẹ̀ ayé.Olúwa ni ó ti sọ ọ́.9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”10Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìíṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.11Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀jáde láti lúwẹ̀ẹ́.Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.12Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀wọn yóò sì wà nílẹ̀,Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,àní sí erùpẹ̀ lásán.