Isaiah22yor_bib

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Jerusalẹmu

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran.Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?2Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàna kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wàlọ́nà jíjìn réré.4Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:jẹ́ kí n sọkún kíkorò.Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínúnítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”
5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kantí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ní àfonífojì ìmọ̀,ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.7Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.
8Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náàsí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù.9Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidiní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,ìwọ ti tọ́jú omisínú adágún ti ìsàlẹ̀.10Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmuó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.11Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjìfún omi inú adágún àtijọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ógbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.
12Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,pè ọ́ ní ọjọ́ náàláti sọkún kí o sì pohùnréré,kí o tu irun rẹ dànù kí o sìda aṣọ ọ̀fọ̀ bora.13Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà;màlúù pípa àti àgùntàn pípa,ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,“Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti péta ni ó sì fún ọ ní àṣẹláti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí,tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gígatí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?
17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígíríkí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtìyóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú síàti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogunàràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!19Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.20“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah.21Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.22Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí.23Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.24Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.25“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.