1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu,a pa Ari run ní Moabu,òru kan ní a pa á run!A pa Kiri run ní Moabu,òru kan ní a pa á run!2Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.Gbogbo orí ni a fágbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.3Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.Wọ́n pohùnréré,wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.4Heṣboni àti Eleale ké sóde,ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbetí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.5Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhitiwọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimuwọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.6Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹàwọn koríko sì ti gbẹ,gbogbo ewéko ti tánewé tútù kankan kò sí mọ́.7Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọwọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.8Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.9Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabuàti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.