Isaiah14yor_bib
1Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu,yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí iyóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.2Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́nwọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdègẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrinní ilẹ̀ Olúwa.Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùnwọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.3Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà,4ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé,báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!5Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,ọ̀pá àwọn aláṣẹ,6èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdèpẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.7Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,wọ́n bú sí orin.8Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọnigi kedari ti Lebanoniń yọ̀ lórí rẹ wí pé,“Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”9Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókèláti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọgbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayéó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọngbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.10Gbogbo wọn yóò dáhùn,wọn yóò wí fún ọ wí pé,“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lúìwọ náà ti dàbí wa.”11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹàwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.12Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé,ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!13Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókèga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.14Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”15Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.16Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.17Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ runtí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”18Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.19Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojìgẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,àwọn tí idà ti gún,àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,20a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.Ìran àwọn ìkàni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.21Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.22“Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”ni Olúwa wí.23Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwíàti sí irà;Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.