Isaiah12yor_bib

Orin ìyìn

1Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé,“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí miìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ìwọ sì ti tù mí nínú.2Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,òun ti di ìgbàlà mi.”3Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omiláti inú kànga ìgbàlà.4Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé,“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,ohun tí ó ti ṣekí o sì kéde pé a ti gbéorúkọ rẹ̀ ga.5Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.6Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣoti Israẹli láàrín yín.”